Samuẹli Keji 22:4-15 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Mo ké pe OLUWA, ẹni tí ìyìn yẹ,Ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.

5. “Ikú yí mi káàkiri, bí ìgbì omi;ìparun sì bò mí mọ́lẹ̀ bíi ríru omi;

6. isà òkú ya ẹnu sílẹ̀ dè mí,ewu ikú sì dojú kọ mí.

7. Ninu ìpọ́njú mi, mo ké pe OLUWAmo ké pe Ọlọrun mi,ó gbọ́ ohùn mi láti inú tẹmpili rẹ̀;ó sì tẹ́tí sí igbe mi.

8. “Ayé mì, ó sì wárìrì;ìpìlẹ̀ àwọn ọ̀run sì wárìrì,ó mì tìtì, nítorí ibinu Ọlọrun.

9. Èéfín jáde láti ihò imú rẹ̀,iná ajónirun sì jáde láti ẹnu rẹ̀;ẹ̀yinná tí ó pọ́n rẹ̀rẹ̀ ń ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ jáde.

10. Ó tẹ àwọn ọ̀run ba, ó sì sọ̀kalẹ̀;ìkùukùu tí ó ṣókùnkùn sì wà ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.

11. Ó gun orí Kerubu, ó fò,afẹ́fẹ́ ni ó fi ṣe ìyẹ́ tí ó fi ń fò.

12. Ó fi òkùnkùn bo ara,ìkùukùu tí ó ṣókùnkùn,tí ó sì kún fún omi ni ó fi ṣe ìbòrí.

13. Ẹ̀yinná tí ń jó ń jáde,láti inú ìmọ́lẹ̀ tí ó wà níwájú rẹ̀.

14. “OLUWA sán ààrá láti ọ̀run wá,ayé sì gbọ́ ohùn ọ̀gá ògo.

15. Ó ta ọpọlọpọ ọfà, ó sì tú wọn ká.Ó tan mànàmáná, wọ́n sì ń sá.

Samuẹli Keji 22