20. Ogun mìíràn tún bẹ́ sílẹ̀ ní Gati. Òmìrán kan wà níbẹ̀ tí ó fẹ́ràn ogun jíjà pupọ, ìka mẹfa mẹfa ni ó ní ní ọwọ́ kọ̀ọ̀kan, ati ẹsẹ̀ kọ̀ọ̀kan; ìka ọwọ́ ati ti ẹsẹ̀ rẹ̀ jẹ́ mẹrinlelogun.
21. Jonatani, ọmọ Ṣimei, arakunrin Dafidi pa á, nígbà tí ó ń fi àwọn ọmọ Israẹli ṣe yẹ̀yẹ́.
22. Láti ìran àwọn òmìrán ìlú Gati ni àwọn mẹrẹẹrin ti wá, Dafidi ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ni ó sì pa wọ́n.