5. Nígbà tí Dafidi ọba dé Bahurimu, ọkunrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣimei, ọmọ Gera, láti inú ìdílé Saulu, jáde sí i, bí ó sì ti ń bọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó ń ṣépè lemọ́lemọ́.
6. Ó ń sọ òkúta lu Dafidi ati gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn eniyan ńláńlá ati ọpọlọpọ eniyan mìíràn wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji Dafidi ọba.
7. Ṣimei ń wí fún Dafidi bí ó ti ń ṣépè pé, “Kúrò lọ́dọ̀ mi! Kúrò lọ́dọ̀ mi! Ìwọ apànìyàn ati eniyan lásán!
8. Ìwọ tí o gba ìjọba mọ́ Saulu lọ́wọ́, OLUWA ń jẹ ọ́ níyà nisinsinyii, fún ọpọlọpọ eniyan tí o pa ninu ìdílé Saulu. OLUWA sì ti fi ìjọba rẹ fún Absalomu, ọmọ rẹ, ìparun ti dé bá ọ, nítorí pé apànìyàn ni ọ́.”
9. Abiṣai, ọmọ Seruaya wí fún ọba pé, “Kí ló dé tí òkú ajá lásánlàsàn yìí fi ń ṣépè lé ọba, oluwa mi? Jẹ́ kí n lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, kí n sì sọ orí rẹ̀ kalẹ̀ kúrò ní ọrùn rẹ̀.”
10. Ṣugbọn ọba dáhùn pé, “Kò sí ohun tí ó kan ẹ̀yin ọmọ Seruaya ninu ọ̀rọ̀ yìí. Kí ni n óo ti ṣe yín sí, ẹ̀yin ọmọ Seruaya? Bí ó bá jẹ́ pé OLUWA ni ó sọ fún un pé kí ó máa ṣépè lé mi, ta ló ní ẹ̀tọ́ láti bèèrè pé, kí ló dé tí ó fi ń ṣe bẹ́ẹ̀?”
11. Dafidi sọ fún Abiṣai ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ṣebí ọmọ tèmi gan-an ni ó ń gbìyànjú láti pa mí yìí, kí ló dé tí ọ̀rọ̀ ti ará Bẹnjamini yìí fi wá jọ yín lójú. OLUWA ni ó ní kí ó máa ṣépè, nítorí náà, ẹ fi sílẹ̀, ẹ jẹ́ kí ó máa ṣẹ́ ẹ.