20. Kò sì tíì pẹ́ pupọ tí o dé, kí ló dé tí o fi fẹ́ máa bá mi káàkiri ninu ìrìnkèrindò mi? Èmi gan-an nìyí, n kò tíì mọ ibi tí mò ń lọ. Pada kí àwọn ará ìlú rẹ gbogbo sì máa bá ọ lọ. OLUWA yóo fẹ́ràn ìwọ náà, yóo sì dúró tì ọ́.”
21. Ṣugbọn Itai dáhùn pé, “Kabiyesi, mo fi OLUWA búra, bí ẹ̀mí oluwa mi ọba tí ń bẹ láàyè, pé, ibikíbi tí o bá ń lọ ni n óo máa bá ọ lọ, kì báà tilẹ̀ já sí ikú.”
22. Dafidi dáhùn, ó ní, “Kò burú.” Itai ati àwọn eniyan rẹ̀, ati àwọn ọmọ kéékèèké, tò kọjá níwájú ọba.
23. Gbogbo ìlú bú sẹ́kún bí àwọn eniyan náà ti ń lọ. Ọba rékọjá odò Kidironi, àwọn eniyan rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Gbogbo wọ́n jọ ń lọ sí ọ̀nà apá ijù.