6. Amnoni bá dùbúlẹ̀, ó ṣe bí ẹni tí ó ń ṣàìsàn.Nígbà tí Dafidi ọba lọ bẹ̀ ẹ́ wò, Amnoni wí fún un pé, “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí Tamari, arabinrin mi, wá ṣe àkàrà díẹ̀ lọ́dọ̀ mi níhìn-ín, níbi tí mo ti lè máa rí i, kí ó sì gbé e wá fún mi.”
7. Dafidi bá ranṣẹ pe Tamari ninu ààfin, ó ní kí ó lọ sinu ilé Amnoni, kí ó lọ tọ́jú oúnjẹ fún un.
8. Tamari lọ, ó bá Amnoni lórí ibùsùn níbi tí ó dùbúlẹ̀ sí. Ó bu ìyẹ̀fun díẹ̀, ó pò ó, ó gé e ní ìwọ̀n àkàrà bíi mélòó kan, níbi tí Amnoni ti lè máa rí i. Lẹ́yìn náà, ó gbé e sórí iná títí tí ó fi jinná,
9. ó sì dà á sinu àwo kan, ó gbé e fún un. Ṣugbọn Amnoni kọ̀, kò jẹ ẹ́, ó ní kí ó sọ fún gbogbo àwọn tí wọ́n wà ninu ilé kí wọ́n jáde, gbogbo wọn bá jáde.