Samuẹli Keji 13:14-23 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Ṣugbọn Amnoni kọ̀, kò gbọ́ ohun tí Tamari sọ fún un. Nígbà tí ó sì jẹ́ pé Amnoni lágbára jù ú lọ, ó fi tipátipá bá a lòpọ̀.

15. Lẹ́yìn náà, Amnoni kórìíra rẹ̀ gidigidi. Ìkórìíra náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó tún wá ju bí ó ti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ lọ. Ó ní kí ó bọ́ sóde, kí ó máa lọ.

16. Tamari dá a lóhùn pé, “Rárá, arakunrin mi, lílé tí ò ń lé mi jáde yìí burú ju ipá tí o fi bá mi lòpọ̀ lọ.”Ṣugbọn Amnoni kọ̀, kò gbọ́ tirẹ̀.

17. Kàkà bẹ́ẹ̀, Amnoni pe iranṣẹ rẹ̀ kan, ó wí fún un pé, “Mú obinrin yìí jáde kúrò níwájú mi, tì í sóde, kí o sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ ọn.”

18. Iranṣẹ náà bá ti Tamari jáde, ó sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ ọn.Aṣọ àwọ̀kanlẹ̀ alápá gígùn, irú èyí tí àwọn ọmọ ọba, obinrin, tí kò tíì wọlé ọkọ máa ń wọ̀, ni Tamari wọ̀.

19. Tamari bá ku eérú sí orí, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó káwọ́ lórí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọkún bí ó ti ń lọ.

20. Nígbà tí Absalomu, ẹ̀gbọ́n Tamari, rí i, ó bi í léèrè pé, “Ṣé Amnoni bá ọ lòpọ̀ ni? Jọ̀wọ́, arabinrin mi, gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn, ọmọ baba kan náà ni ẹ̀yin mejeeji, nítorí náà, má sọ fún ẹnikẹ́ni.” Tamari bá ń gbé ilé Absalomu. Òun nìkan ni ó dá wà, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ pupọ.

21. Nígbà tí Dafidi ọba gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, inú bí i gidi.

22. Absalomu kórìíra Amnoni gan-an nítorí pé ó fi ipá bá Tamari, àbúrò rẹ̀, lòpọ̀, ṣugbọn kò bá a sọ nǹkankan; ìbáà ṣe rere ìbáà sì ṣe burúkú.

23. Lẹ́yìn ọdún meji tí nǹkan yìí ṣẹlẹ̀, Absalomu lọ rẹ́ irun aguntan rẹ̀ ní Baali Hasori, lẹ́bàá ìlú Efuraimu, ó sì pe gbogbo àwọn ọmọ ọba patapata lọkunrin sibẹ.

Samuẹli Keji 13