Samuẹli Keji 12:24-28 BIBELI MIMỌ (BM)

24. Dafidi bá tu Batiṣeba, aya rẹ̀ ninu, ó bá a lòpọ̀, ó sì bí ọmọkunrin kan fún un. Dafidi sọ ọmọ yìí ní Solomoni. OLUWA fẹ́ràn ọmọ náà,

25. ó sì rán Natani wolii pé kí ó sọ ọmọ náà ní Jedidaya, nítorí pé, OLUWA fẹ́ràn rẹ̀.

26. Ní gbogbo àkókò yìí, Joabu wà níbi tí ó ti gbógun ti Raba, olú ìlú àwọn ará Amoni, ó sì gba ìlú ọba wọn.

27. Ó ranṣẹ sí Dafidi láti ròyìn fún un pé, “Mo ti gbógun ti Raba, mo sì ti gba ìlú tí orísun omi wọn wà,

28. kó àwọn ọmọ ogun yòókù jọ, kí o kọlu ìlú náà, kí o sì gbà á fúnra rẹ. N kò fẹ́ gba ìlú náà kí ògo gbígbà rẹ̀ má baà jẹ́ tèmi.”

Samuẹli Keji 12