13. Ẹ̀ṣẹ̀ ni ó ṣiwaju Òfin dáyé, bẹ́ẹ̀ bí kò bá sí òfin a kì í ka ẹ̀ṣẹ̀ sí eniyan lọ́rùn.
14. Ṣugbọn ikú ti jọba ní tirẹ̀ láti ìgbà Adamu títí dé ìgbà Mose, àwọn tí kò tilẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ nípa rírú òfin bíi Adamu, pẹlu àwọn tí ikú pa, Adamu tí ó jẹ́ àpẹẹrẹ irú ẹni tó ń bọ̀.
15. Kì í ṣe bí eniyan ṣe rú òfin tó ni Ọlọrun fi ń wọn ìfẹ́ ati àánú rẹ̀. Bí gbogbo eniyan bá jogún ikú nítorí aṣemáṣe ẹnìkan, oore-ọ̀fẹ́ ati àánú tí Ọlọrun fún gbogbo eniyan láti ọwọ́ ẹnìkan, àní Jesu Kristi, ó pọ̀ pupọ; ó pọ̀ ju ogún ikú lọ.
16. Kì í ṣe ẹnìkan tí ó dẹ́ṣẹ̀ ni Ọlọrun ń wò kí ó tó ta àwọn eniyan lọ́rẹ. Ẹnìkan ló fa ìdájọ́ Ọlọrun. Ẹ̀bi ni a sì rí gbà ninu rẹ̀. Ṣugbọn àánú tí Ọlọrun fún wa dípò ọpọlọpọ aṣemáṣe wa, ìdáláre ni ó yọrí sí.