8. Ṣé, “Kí á kúkú máa ṣe ibi kí rere lè ti ibẹ̀ jáde?” Bí àwọn onísọkúsọ kan ti ń sọ pé à ń sọ. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ yẹ fún ìdálẹ́bi.
9. Kí ni kí á rí dìmú ninu ọ̀rọ̀ yìí? Ṣé àwa Juu sàn ju àwọn orílẹ̀-èdè yòókù lọ ni? Rárá o! Nítorí a ti wí ṣáájú pé ati Juu ati Giriki, gbogbo wọn ni ó wà ní ìkáwọ́ ẹ̀ṣẹ̀.
10. Ó wà ní àkọsílẹ̀ bẹ́ẹ̀ pé,“Kò sí ẹnìkan tí ó jẹ́ olódodo; kò sí ẹnìkankan.
11. Kò sí ẹni tí òye yé,kò sí ẹni tí ó ń wá Ọlọrun.
12. Gbogbo wọn ti yapa kúrò lójú ọ̀nà,gbogbo wọn kò níláárí mọ́,kò sí ẹni tí ó ń ṣe rere,kò sí ẹnìkan.
13. Ibojì tí ó yanu sílẹ̀ ni ọ̀nà ọ̀fun wọn,ẹ̀tàn kún ẹnu wọn;oró paramọ́lẹ̀ wà létè wọn;
14. ẹnu wọn kún fún èpè ati ọ̀rọ̀ burúkú.
15. Ẹsẹ̀ wọn yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.
16. Ọ̀nà jamba ati òṣì ni wọ́n ń rìn.
17. Wọn kò mọ ọ̀nà alaafia.
18. Kò sí ìbẹ̀rù Ọlọrun ní ọkàn wọn.”
19. A mọ̀ pé ohunkohun tí Òfin bá wí, ó wà fún àwọn tí ó mọ Òfin ni, kí ẹnikẹ́ni má ṣe rí àwáwí wí, kí gbogbo aráyé lè wà lábẹ́ ìdájọ́ Ọlọrun.
20. Nítorí gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀, bí a bá mú Òfin tí a fi díwọ̀n iṣẹ́ ọmọ eniyan, kò sí ẹ̀dá kan tí a óo dá láre níwájú Ọlọrun. Nítorí òfin níí mú kí eniyan mọ ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́ṣẹ̀.
21. Ṣugbọn ní àkókò yìí, ọ̀nà tí Ọlọrun fi ń dá eniyan láre ti hàn láìsí Òfin, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àkọsílẹ̀ ti Òfin ati ti àwọn wolii Ọlọrun jẹ́rìí sí i.
22. Gbogbo àwọn tí ó bá gba Jesu gbọ́ yóo yege lọ́dọ̀ Ọlọrun láìsí ìyàtọ̀ kan.
23. Nítorí gbogbo eniyan ló ti dẹ́ṣẹ̀, tí wọ́n sì kùnà ògo Ọlọrun.