Romu 12:8-21 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Bí ó bá ní ẹ̀bùn láti fúnni ní ọ̀rọ̀ ìwúrí, kí ó lò ó láti lé ìrẹ̀wẹ̀sì jìnnà. Ẹni tí ó bá ń ṣe ìtọrẹ àánú, kí ó ṣe é pẹlu ọkàn kan. Ẹni tí ó bá ní ẹ̀bùn láti ṣe aṣiwaju, kí ó ṣe é tọkàntọkàn. Ẹni tí ó bá ń ṣiṣẹ́ àánú, kí ó fọ̀yàyà ṣe é.

9. Ìfẹ́ yín kò gbọdọ̀ ní ẹ̀tàn ninu. Ẹ kórìíra nǹkan burúkú. Ẹ fara mọ́ àwọn nǹkan rere.

10. Ẹ ní ìfẹ́ láàrin ara yín bíi mọ̀lẹ́bí. Ní ti bíbu ọlá fún ara yín, ẹ máa fi ti ẹnìkejì yín ṣiwaju.

11. Ẹ má jẹ́ kí ìtara yín rẹ̀yìn. Ẹ máa sin Oluwa tọkàntọkàn.

12. Ẹ máa yọ̀ nítorí ìrètí tí ẹ ní. Ẹ máa fara da ìṣòro, kí ẹ sì tẹra mọ́ adura.

13. Ẹ pín àwọn aláìní láàrin àwọn onigbagbọ ninu ohun ìní yín. Ẹ máa ṣaájò àwọn àlejò.

14. Ẹ máa súre fún àwọn tí ó ń ṣe inúnibíni yín, kàkà kí ẹ ṣépè, ìre ni kí ẹ máa sú fún wọn.

15. Àwọn tí ń yọ̀, ẹ bá wọn yọ̀, àwọn tí ń sunkún, ẹ bá wọn sunkún.

16. Ẹ ní inú kan sí ara yín. Ẹ má ṣe gbèrò ohun gíga-gíga, ṣugbọn ẹ máa darapọ̀ mọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara yín.

17. Ẹ má máa fi burúkú san burúkú. Ẹ jẹ́ kí èrò ọkàn yín sí gbogbo eniyan máa jẹ́ rere.

18. Ẹ sa ipá yín, níwọ̀n bí ó bá ti ṣeéṣe, láti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu gbogbo eniyan.

19. Ẹ̀yin olùfẹ́, ẹ má máa gbẹ̀san, dípò bẹ́ẹ̀, ẹ máa fún Ọlọrun láàyè láti fi ibinu rẹ̀ hàn. Nítorí Ọlọrun sọ ninu àkọsílẹ̀ pé, “Tèmi ni ẹ̀san, Èmi yóo sì gbẹ̀san.”

20. Ó wà ní àkọsílẹ̀ mìíràn pé, “Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ, bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mu. Nítorí nípa ṣíṣe báyìí, ìwọ yóo wa ẹ̀yinná ìtìjú lé e lórí.”

21. Má jẹ́ kí nǹkan burúkú borí rẹ, ṣugbọn fi ohun rere ṣẹgun nǹkan burúkú.

Romu 12