Orin Solomoni 7:2-7 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Ìdodo rẹ dàbí abọ́,tí kì í gbẹ fún àdàlú waini,ikùn rẹ dàbí òkítì ọkà,tí a fi òdòdó lílì yíká.

3. Ọmú rẹ mejeeji dàbí ọmọ àgbọ̀nrín meji,tí wọn jẹ́ ìbejì.

4. Ọrùn rẹ dàbí ilé-ìṣọ́ tí wọn fi eyín erin kọ́.Ojú rẹ dàbí adágún omi ìlú Heṣiboni,tí ó wà ní ẹnubodè Batirabimu.Imú rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Lẹbanoni,tí ó dojú kọ ìlú Damasku.

5. Orí rẹ dàbí adé lára rẹ, ó rí bí òkè Kamẹli,irun rẹ dàbí aṣọ elése-àlùkò tí ó ṣẹ́ léra, wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́irun orí rẹ ń dá ọba lọ́rùn.

6. O dára, o wuni gan-an,olùfẹ́ mi, ẹlẹgẹ́ obinrin.

7. Ìdúró rẹ dàbí igi ọ̀pẹ,ọyàn rẹ ṣù bí ìdì èso àjàrà.

Orin Solomoni 7