Orin Solomoni 4:2-8 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Eyín rẹ dàbí ọ̀wọ́ aguntan tí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ gé irun wọn,tí wọn wá fọ̀;gbogbo wọn gún régé,Kò sí ọ̀kan kan tí ó yọ ninu wọn.

3. Ètè rẹ dàbí òwú pupa;ẹnu rẹ fanimọ́ra,ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ ń dán bí ìlàjì èso Pomegiranate,lábẹ́ ìbòjú rẹ.

4. Ọrùn rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Dafidi,tí a kọ́ fún ihamọra,ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ dàbí ẹgbẹrun (1000) asà tí a kó kọ́,bí apata àwọn akọni jagunjagun tí a kó jọ.

5. Ọmú rẹ mejeeji dàbí ọmọ àgbọ̀nrín meji, tí wọn jẹ́ ìbejì,tí wọn ń jẹko láàrin òdòdó lílì.

6. N óo wà lórí òkè òjíá,ati lórí òkè turari,títí ilẹ̀ yóo fi mọ́,tí òkùnkùn yóo sì lọ.

7. O dára gan-an ni, olùfẹ́ mi!O dára dára, o ò kù síbìkan,kò sí àbààwọ́n kankan lára rẹ.

8. Máa bá mi bọ̀ láti òkè Lẹbanoni, iyawo mi,máa bá mi bọ̀ láti òkè Lẹbanoni.Kúrò ní ṣóńṣó òkè Amana,kúrò lórí òkè Seniri ati òkè Herimoni,kúrò ninu ihò kinniun, ati ibi tí àwọn ẹkùn ń gbé.

Orin Solomoni 4