1. Wò ó! O dára gan-an ni, olólùfẹ́ mi,ẹwà rẹ pọ̀.Ẹyinjú rẹ dàbí ti àdàbà lábẹ́ ìbòjú rẹ,irun orí rẹ dàbí ọ̀wọ́ ewúrẹ́,tí wọn ń sọ̀kalẹ̀ láti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Gileadi.
2. Eyín rẹ dàbí ọ̀wọ́ aguntan tí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ gé irun wọn,tí wọn wá fọ̀;gbogbo wọn gún régé,Kò sí ọ̀kan kan tí ó yọ ninu wọn.
3. Ètè rẹ dàbí òwú pupa;ẹnu rẹ fanimọ́ra,ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ ń dán bí ìlàjì èso Pomegiranate,lábẹ́ ìbòjú rẹ.