Orin Solomoni 1:14-17 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Olùfẹ́ mi dàbí ìdì òdòdó igi Sipirẹsi,ninu ọgbà àjàrà Engedi.

15. Wò ó! O mà dára o, olólùfẹ́ mi;o lẹ́wà pupọ.Ojú rẹ tutù bíi ti àdàbà.

16. Háà, o mà dára o! Olùfẹ́ mi,o lẹ́wà gan-an ni.Ewéko tútù ni yóo jẹ́ ibùsùn wa.

17. Igi Kedari ni òpó ilé wa,igi firi sì ni ọ̀pá àjà ilé wa.

Orin Solomoni 1