Orin Dafidi 98:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ kọ orin titun sí OLUWA,nítorí tí ó ti ṣe ohun ìyanu;agbára ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ati apá mímọ́ rẹ̀ ni ó fi ṣẹgun.

2. OLUWA ti sọ ìṣẹ́gun rẹ̀ di mímọ̀,ó ti fi ìdáláre rẹ̀ hàn lójú àwọn orílẹ̀-èdè.

3. Ó ranti ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, ati òtítọ́ rẹ̀sí àwọn ọmọ Israẹli;gbogbo ayé ti rí ìṣẹ́gun Ọlọrun wa.

4. Gbogbo ayé, ẹ hó ìhó ayọ̀ sí OLUWA;ẹ bú sí orin ayọ̀, kí ẹ sì kọ orin ìyìn.

5. Ẹ fi hapu kọ orin ìyìn sí OLUWA,àní, hapu ati ohùn orin dídùn.

Orin Dafidi 98