Orin Dafidi 90:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA, ìwọ ni o ti jẹ́ ibi ààbò wa láti ìrandíran.

2. Kí o tó dá àwọn òkè,ati kí o tó dá ilẹ̀ ati ayé,láti ayérayé, ìwọ ni Ọlọrun.

3. O sọ eniyan di erùpẹ̀ pada,o sì wí pé, “Ẹ yipada, ẹ̀yin ọmọ eniyan.”

4. Nítorí pé lójú rẹ, ẹgbẹrun ọdún dàbí àná,tabi bí ìṣọ́ kan ní òru.

5. Ìwọ a máa gbá ọmọ eniyan dànù; wọ́n dàbí àlá,bíi koríko tí ó tutù ní òwúrọ̀;

Orin Dafidi 90