Orin Dafidi 9:7-14 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Ṣugbọn OLUWA gúnwà títí lae,ó ti fi ìdí ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀ múlẹ̀.

8. Yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé,yóo sì fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè.

9. OLUWA ni ààbò fún àwọn tí a ni lára,òun ni ibi ìsádi ní ìgbà ìpọ́njú.

10. Àwọn tí ó mọ̀ ọ́ yóo gbẹ́kẹ̀lé ọ;nítorí ìwọ, OLUWA, kìí kọ àwọn tí ń wá ọ sílẹ̀.

11. Ẹ kọrin ìyìn sí OLUWA, tí ó gúnwà ní Sioni!Ẹ kéde iṣẹ́ rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè!

12. Nítorí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ranti,kò sì gbàgbé igbe ẹkún àwọn tí a pọ́n lójú.

13. OLUWA, ṣàánú fún mi!Wò ó bí àwọn ọ̀tá mi ṣe ń pọ́n mi lójú.Gbà mí kúrò létí bèbè ikú,

14. kí n lè kọrin ìyìn rẹ,kí n sì lè yọ ayọ̀ ìgbàlà rẹ lẹ́nu ibodè Sioni.

Orin Dafidi 9