Orin Dafidi 89:5-14 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Jẹ́ kí ojú ọ̀run máa kọrin ìyìn iṣẹ́ ìyanu rẹ, OLÚWA;kí àwọn eniyan mímọ́ sì máa kọrin ìyìn òtítọ́ rẹ.

6. Nítorí ta ni a lè fi wé ọ ní ọ̀run, OLUWA?Ta ni ó dàbí OLUWA láàrin àwọn ẹ̀dá ọ̀run?

7. Ọlọrun, ìwọ ni a bẹ̀rù ninu ìgbìmọ̀ àwọn eniyan mímọ́,o tóbi, o sì lẹ́rù ju gbogbo àwọn tí ó yí ọ ká lọ?

8. OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, ta ló lágbára bíi rẹ?OLUWA, òtítọ́ rẹ yí ọ ká.

9. Ò ń jọba lórí òkun tí ń ru;nígbà tí ìgbì rẹ̀ bá ru sókè, ìwọ ni ò ń mú kí ó rọlẹ̀.

10. Ìwọ ni o wó Rahabu mọ́lẹ̀ bí òkú ẹran;o fi ọwọ́ agbára rẹ fọ́n àwọn ọ̀tá rẹ ká.

11. Tìrẹ ni ọ̀run, tìrẹ sì ni ayé pẹlu;ìwọ ni o tẹ ayé ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ dó.

12. Ìwọ ni o dá àríwá ati gúsù,òkè Tabori ati òkè Herimoni ń fi ayọ̀yin orúkọ rẹ.

13. Alágbára ni ọ́;agbára ń bẹ ní ọwọ́ rẹ;o gbé ọwọ́ agbára rẹ sókè.

14. Òdodo ati ẹ̀tọ́ ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ;ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ ń lọ ṣiwaju rẹ.

Orin Dafidi 89