Orin Dafidi 88:8-13 BIBELI MIMỌ (BM)

8. O ti mú kí àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi fi mí sílẹ̀;mo sì ti di ẹni ìríra lọ́dọ̀ wọn:mo wà ninu àhámọ́, n kò sì lè jáde;

9. ojú mi ti di bàìbàì nítorí ìbànújẹ́.Lojoojumọ ni mò ń ké pè ọ́, OLUWA;tí mò ń tẹ́wọ́ adura sí ọ.

10. Ṣé òkú ni o óo ṣe iṣẹ́ ìyanu hàn?Ṣé àwọn òkú lè dìde kí wọ́n máa yìn ọ́?

11. Ṣé a lè sọ̀rọ̀ ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ninu ibojì?Àbí ẹnìkan lè sọ̀rọ̀ òtítọ́ rẹ ninu ìparun?

12. Ṣé a lè rí iṣẹ́ ìyanu rẹ ninu òkùnkùn ikú?Àbí ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà rẹ wà ní ilẹ̀ àwọn tí a ti gbàgbé?

13. Ṣugbọn OLUWA, èmi ń ké pè ọ́;ní òwúrọ̀ n óo gbadura sí ọ.

Orin Dafidi 88