Orin Dafidi 86:16-17 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Kọjú sí mi, kí o sì ṣàánú mi;fún èmi iranṣẹ rẹ ní agbára rẹ;kí o sì gba èmi ọmọ iranṣẹbinrin rẹ là.

17. Fi àmì ojurere rẹ hàn mí,kí àwọn tí ó kórìíra mi lè rí i,kí ojú sì tì wọ́n;nítorí pé ìwọ, OLUWA, ni o ràn mí lọ́wọ́,tí o sì tù mí ninu.

Orin Dafidi 86