Orin Dafidi 83:2-6 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Wò ó! Àwọn ọ̀tá rẹ ń ṣọ̀tẹ̀ sí ọ;àwọn tí ó kórìíra rẹ sì ń yájú sí ọ.

3. Wọ́n pète àrékérekè sí àwọn eniyan rẹ;wọ́n sì gbìmọ̀ pọ̀ sí àwọn tí ó sá di ọ́.

4. Wọ́n ní, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á pa orílẹ̀-èdè wọn run;kí á má ranti orúkọ Israẹli mọ́!”

5. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n jùmọ̀ pète pèrò;wọ́n dá majẹmu láti dojú kọ ọ́.

6. Àwọn ará Edomu, ati àwọn ọmọ Iṣimaeli,àwọn ará Moabu, ati àwọn ọmọ Hagiri,

Orin Dafidi 83