Orin Dafidi 78:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ̀yin eniyan mi, ẹ dẹtí sí ẹ̀kọ́ mi;ẹ tẹ́tí si ọ̀rọ̀ ẹnu mi.

2. N óo la ẹnu mi tòwe-tòwe;n óo fa ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ àtijọ́ yọ,

3. ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti mọ̀,ohun tí àwọn baba ńlá wa ti sọ fún wa.

Orin Dafidi 78