6. Nípa ìbáwí rẹ, Ọlọrun Jakọbu,ati ẹṣin, ati ẹni tó gun ẹṣin,gbogbo wọn ló ṣubú lulẹ̀, tí wọn kò sì lè mira.
7. Ṣugbọn ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ni ọ́!Ta ló tó dúró níwájú rẹtí ibinu rẹ bá dé?
8. Láti ọ̀run wá ni o ti ń ṣe ìdájọ́,ẹ̀rù ba ayé, ayé sì dúró jẹ́ẹ́;
9. nígbà tí Ọlọrun dìde láti gbé ìdájọ́ kalẹ̀,láti gba gbogbo àwọn tí à ń nilára láyé sílẹ̀.