Orin Dafidi 74:14-17 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Ìwọ ni o fọ́ orí Lefiatani túútúú;o sì fi òkú rẹ̀ ṣe ìjẹ fún àwọn ẹranko inú aṣálẹ̀.

15. Ìwọ ni o fọ́ àpáta tí omi tú jáde, tí odò sì ń ṣàn,ìwọ ni o sọ odò tí ń ṣàn di ilẹ̀ gbígbẹ.

16. Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ náà sì ni òru,ìwọ ni o gbé òṣùpá ati oòrùn ró.

17. Ìwọ ni o pa gbogbo ààlà ilẹ̀ ayé;ìwọ ni o dá ìgbà òjò ati ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn.

Orin Dafidi 74