Orin Dafidi 68:31-35 BIBELI MIMỌ (BM)

31. Jẹ́ kí àwọn ikọ̀ wá láti Ijipti,kí àwọn ará Kuṣi tẹ́wọ́ adura sí Ọlọrun.

32. Ẹ kọ orin sí Ọlọrun ẹ̀yin ìjọba ayé;ẹ kọ orin ìyìn sí OLUWA.

33. Ẹni tí ń gun awọsanma lẹ́ṣin, àní awọsanma àtayébáyé;ẹ gbọ́ bí ó ṣe ń sán ààrá, ẹ gbọ́ ohùn alágbára.

34. Ẹ bu ọlá fún Ọlọrun,ẹni tí ògo rẹ̀ wà lórí Israẹli;tí agbára rẹ̀ sì hàn lójú ọ̀run.

35. Ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ni Ọlọrun ní ibi mímọ́ rẹ̀,Ọlọrun Israẹli;òun ni ó ń fún àwọn eniyan rẹ̀ ní ọlá ati agbára.Ìyìn ni fún Ọlọrun!

Orin Dafidi 68