Orin Dafidi 64:8-10 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Yóo pa wọ́n run nítorí ohun tí wọ́n fi ẹnu wọn sọ;gbogbo ẹni tí ó bá rí wọn ni yóo máa mirí nítorí wọn.

9. Ẹ̀rù yóo sì ba gbogbo eniyan;wọn yóo máa sọ ohun tí Ọlọrun ti gbé ṣe,wọn yóo sì máa ronú nípa iṣẹ́ rẹ̀.

10. Kí àwọn olódodo máa yọ̀ ninu OLUWA,kí wọ́n sì máa wá ààbò lọ́dọ̀ rẹ̀!Kí gbogbo ẹni pípé máa ṣògo.

Orin Dafidi 64