Orin Dafidi 61:4-8 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Jẹ́ kí n máa gbé inú àgọ́ rẹ títí lae,kí n lè máa wà láìléwu lábẹ́ ààbò ìyẹ́ rẹ.

5. Nítorí ìwọ, Ọlọrun, ti gbọ́ ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́;o ti fún mi ní ogún tí o pèsè fún àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ.

6. Jẹ́ kí ẹ̀mí ọba ó gùn;kí ó pẹ́ láyé kánrinkése.

7. Kí ó máa gúnwà níwájú Ọlọrun títí lae;máa fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, ati òtítọ́ rẹ ṣọ́ ọ.

8. Bẹ́ẹ̀ ni n óo máa kọ orin ìyìn orúkọ rẹ títí lae,nígbà tí mo bá ń san ẹ̀jẹ́ mi lojoojumọ.

Orin Dafidi 61