Orin Dafidi 6:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA, má fi ibinu bá mi wí;má sì fi ìrúnú jẹ mí níyà.

2. Ṣàánú mi, OLUWA, nítorí àárẹ̀ mú ọkàn mi,OLUWA, wò mí sàn nítorí ara ń ni mí dé egungun.

3. Ọkàn mi kò balẹ̀ rárá,yóo ti pẹ́ tó, OLUWA, yóo ti pẹ́ tó?

4. OLUWA, pada wá gbà mí,gbà mí là nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.

5. Nítorí kò sí ẹni tí yóo ranti rẹ lẹ́yìn tí ó bá ti kú.Àbí, ta ló lè yìn ọ́ ninu isà òkú?

Orin Dafidi 6