1. Gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, Ọlọrun mi;dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn tí ó gbógun tì mí.
2. Gbà mí lọ́wọ́ àwọn aṣebi,kí o sì yọ mí lọ́wọ́ àwọn apànìyàn.
3. Wò ó bí wọ́n ṣe lúgọ dè mí!OLUWA, àwọn jàǹdùkú eniyan kó ara wọn jọláti pa mí lára, láìṣẹ̀, láìrò.