Orin Dafidi 56:3-6 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Nígbà tí ẹ̀rù bá ń bà mí,èmi yóo gbẹ́kẹ̀lé ọ.

4. Ọlọrun, mo yìn ọ́ fún ọ̀rọ̀ rẹ,ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé láìbẹ̀rù;kí ni eniyan ẹlẹ́ran ara lè fi mí ṣe?

5. Tọ̀sán-tòru ni wọ́n ń da ọ̀rọ̀ mi rú;ibi ni gbogbo èrò tí wọn ń gbà sí mi.

6. Wọ́n kó ara wọn jọ, wọ́n sápamọ́,wọ́n ń ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ mi,bí wọn ṣé ń dọdẹ ẹ̀mí mi.

Orin Dafidi 56