3. Nítorí mo mọ ibi tí mo ti ṣẹ̀,nígbà gbogbo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi sì wà níwájú mi.
4. Ìwọ nìkan, àní, ìwọ nìkan ṣoṣo ni mo ṣẹ̀,tí mo ṣe ohun tí ó burú lójú rẹ,kí ẹjọ́ rẹ lè tọ́ nígbà tí o bá ń dájọ́,kí ọkàn rẹ lè mọ́ nígbà tí o bá ń ṣe ìdájọ́.
5. Dájúdájú, ninu àìdára ni a bí mi,ninu ẹ̀ṣẹ̀ ni ìyá mi sì lóyún mi.
6. O fẹ́ràn òtítọ́ inú;nítorí náà, kọ́ mi lọ́gbọ́n ní kọ́lọ́fín ọkàn mi.
7. Fi ewé hisopu fọ̀ mí, n óo sì mọ́;wẹ̀ mí, n óo sì funfun ju ẹ̀gbọ̀n òwú lọ.
8. Fún mi ní ayọ̀ ati inú dídùn,kí gbogbo egungun mi tí ó ti rún lè máa yọ̀.