15. OLUWA, là mí ní ohùn,n óo sì máa ròyìn iṣẹ́ ńlá rẹ.
16. Bí ó bá jẹ́ pé o fẹ́ ẹbọ ni, ǹ bá mú wá fún ọ;ṣugbọn o ò tilẹ̀ fẹ́ ẹbọ sísun.
17. Ẹbọ tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ ìwọ Ọlọrun ni ẹ̀mí ìròbìnújẹ́,ọkàn ìròbìnújẹ́ ati ìrònúpìwàdà ni ìwọ kì yóo gàn.
18. Jẹ́ kí ó dára fún Sioni ninu ìdùnnú rẹ;tún odi Jerusalẹmu mọ.
19. Nígbà náà ni inú rẹ yóo dùn sí ẹbọ tí ó tọ́,ẹbọ sísun, ati ẹbọ tí a sun lódidi;nígbà náà ni a óo fi akọ mààlúù rúbọ lórí pẹpẹ rẹ.