Orin Dafidi 50:11-18 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ni mo mọ̀,tèmi sì ni gbogbo nǹkan tí ń rìn ninu pápá.

12. “Bí ebi bá tilẹ̀ pa mí, ẹ̀yin kọ́ ni n óo sọ fún,nítorí èmi ni mo ni gbogbo ayé ati àwọn nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀.

13. Ṣé èmi a máa jẹ ẹran akọ mààlúù?Àbí mà máa mu ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́?

14. Ọpẹ́ ni kí ẹ fi rúbọ sí Ọlọrun,kí ẹ sì máa san ẹ̀jẹ́ yín fún Ọ̀gá Ògo.

15. Ẹ ké pè mí ní ọjọ́ ìṣòro;n óo gbà yín, ẹ óo sì yìn mí lógo.”

16. Ṣugbọn Ọlọrun bi àwọn eniyan burúkú pé,“Ẹ̀tọ́ wo ni ẹ níláti máa ka àwọn òfin mi,tabi láti máa mú ẹnu ba ìlànà mi?

17. Nítorí ẹ kórìíra ẹ̀kọ́;ẹ sì ti ta àṣẹ mi nù.

18. Tí ẹ bá rí olè, ẹ̀yin pẹlu rẹ̀ a dọ̀rẹ́;ẹ sì ń bá àwọn panṣaga kẹ́gbẹ́.

Orin Dafidi 50