Orin Dafidi 50:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA, Ọlọrun Alágbára ti sọ̀rọ̀:ó ké sí gbogbo ayéláti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

2. Ọlọrun yọ bí ọjọ́ láti Sioni,ìlú tó dára, tó lẹ́wà.

3. Ọlọrun wa ń bọ̀, kò dákẹ́:iná ajónirun ń jó níwájú rẹ̀;ìjì líle sì ń jà yí i ká.

4. Ó ké sí ọ̀run lókè;ó pe ayé pẹlu láti gbọ́ ìdájọ́ tí yóo ṣe fún àwọn eniyan rẹ̀.

5. Ó ní, “Ẹ kó àwọn olùfọkànsìn mi jọ sọ́dọ̀ mi,àwọn tí wọ́n ti fi ẹbọ bá mi dá majẹmu!”

6. Ojú ọ̀run ń kéde òdodo rẹ̀ péỌlọrun ni onídàájọ́.

7. “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan mi, n óo sọ̀rọ̀,Israẹli, n óo takò yín.Èmi ni Ọlọrun, Ọlọrun yín.

Orin Dafidi 50