Orin Dafidi 44:18-21 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Ọkàn wa kò pada lẹ́yìn rẹ,bẹ́ẹ̀ ni a kò yẹsẹ̀ kúrò ninu ìlànà rẹ,

19. sibẹ o fọ́ wa túútúú fún ìjẹ àwọn ẹranko,o sì fi òkùnkùn biribiri bò wá mọ́lẹ̀.

20. Bí ó bá jẹ́ pé a gbàgbé orúkọ Ọlọrun wa,tabi tí a bá bọ oriṣa,

21. ṣebí Ọlọrun ìbá ti mọ̀?Nítorí òun ni olùmọ̀ràn ọkàn.

Orin Dafidi 44