Orin Dafidi 35:7-27 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Nítorí wọ́n dẹ àwọ̀n sílẹ̀ fún mi láìnídìí,wọ́n sì gbẹ́ kòtò sílẹ̀ dè mí láìnídìí.

8. Jẹ́ kí ìparun dé bá wọn lójijì,jẹ́ kí àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀ dè mí mú wọn;jẹ́ kí wọ́n kó sinu rẹ̀, kí wọ́n sì parun!

9. Nígbà náà ni n óo máa yọ̀ ninu OLUWA,n óo sì yọ ayọ̀ ńlá nítorí ìgbàlà rẹ̀.

10. N óo fi gbogbo ara wí pé,“OLUWA, ta ni ó dàbí rẹ?Ìwọ ni ò ń gba aláìlágbáralọ́wọ́ ẹni tí ó lágbáratí o sì ń gba aláìlágbára ati aláìnílọ́wọ́ ẹni tí ó fẹ́ fi wọ́n ṣe ìjẹ.”

11. Àwọn tí ń fi ìlara jẹ́rìí èké dìde sí mi;wọ́n ń bi mí léèrè ohun tí n kò mọ̀dí.

12. Wọ́n fi ibi san oore fún mi,ọkàn mi sì rẹ̀wẹ̀sì.

13. Bẹ́ẹ̀ sì ni, ní tèmi, nígbà tí wọn ń ṣàìsàn,aṣọ ọ̀fọ̀ ni mo wọ̀;mo fi ààwẹ̀ jẹ ara mi níyà;mo gbadura pẹlu ìtẹríba patapata,

14. bí ẹni pé mò ń ṣọ̀fọ̀ ọ̀rẹ́ mi, tabi arakunrin mi;mò ń lọ káàkiri, bí ẹni tí ń pohùnréré ẹkún ìyá rẹ̀,mo doríkodò, mo sì ń ṣọ̀fọ̀.

15. Ṣugbọn nígbà tí èmi kọsẹ̀, wọ́n kó ara wọn jọ,wọ́n ń yọ̀,wọ́n kó tì mí;pàápàá jùlọ, àwọn àlejò tí n kò mọ̀ ríbẹ̀rẹ̀ sí purọ́ mọ́ mi léraléra.

16. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí pẹ̀gàn mi, wọ́n ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà;wọ́n sì ń wò mí bíi pé kí n kú.

17. OLUWA, yóo ti pẹ́ tó, tí o óo máa wò mí níran?Yọ mí kúrò ninu ogun tí wọn gbé tì mí,gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn kinniun!

18. Nígbà náà ni n óo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ láàrin àwùjọ ọ̀pọ̀ eniyan;láàrin ọpọlọpọ eniyan ni n óo máa yìn ọ́.

19. Má jẹ́ kí àwọn tí ń bá mi ṣọ̀tá láìnídìí yọ̀ mí,má sì jẹ́ kí àwọn tí ó kórìíra mi wò mí ní ìwò ẹ̀sín.

20. Nítorí pé wọn kì í sọ̀rọ̀ alaafia sí àwọn tí wọn ń lọ jẹ́ẹ́jẹ́ wọnàfi kí wọ́n máa pète oríṣìíríṣìí ẹ̀tàn.

21. Wọ́n la ẹnu, wọ́n ń pariwo lé mi lórí,wọ́n ń wí pé, “Ìn hín ìn, a rí ọ, ojú wa ló ṣe!”

22. O ti rí i, OLUWA, má dákẹ́.OLUWA, má jìnnà sí mi.

23. Paradà, OLUWA, jí gìrì sí ọ̀ràn mi,gbèjà mi, Ọlọrun mi, ati OLUWA mi!

24. Dá mi láre, OLUWA, Ọlọrun mi, gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ;má sì jẹ́ kí wọ́n yọ̀ mí!

25. Má jẹ́ kí wọ́n wí láàrin ara wọn pé,“Ìn hín ìn, ọwọ́ wa ba ohun tí a fẹ́!”Má jẹ́ kí wọn wí pé,“A rẹ́yìn ọ̀tá wa.”

26. Jẹ́ kí ojú ti gbogbo àwọn tí ń yọ̀ pé ìpọ́njú dé bá mi;kí ìdààmú bá wọn;bá mi da aṣọ ìtìjú ati ẹ̀tẹ́ bo àwọn tí ń gbé àgbéré sí mi.

27. Kí àwọn tí ń wá ìdáláre mimáa hó ìhó ayọ̀, kí inú wọn sì máa dùn,kí wọ́n máa wí títí ayé pé,“OLUWA tóbi,inú rẹ̀ dùn sí alaafia àwọn iranṣẹ rẹ̀.”

Orin Dafidi 35