Orin Dafidi 34:2-5 BIBELI MIMỌ (BM)

2. OLUWA ni èmi óo máa fi yangàn;kí inú àwọn olùpọ́njú máa dùn nígbà tí wọ́n bá gbọ́.

3. Ẹ bá mi gbé OLUWA ga,ẹ jẹ́ kí á jùmọ̀ gbé orúkọ rẹ̀ lékè!

4. Mo ké pe OLUWA, ó sì dá mi lóhùn,ó sì gbà mí lọ́wọ́ gbogbo ohun tí ń bà mí lẹ́rù.

5. Wọ́n gbójú sókè sí OLUWA, wọ́n láyọ̀;ojú kò sì tì wọ́n.

Orin Dafidi 34