Orin Dafidi 31:20-23 BIBELI MIMỌ (BM)

20. O fi ìyẹ́ apá rẹ ṣíji bò wọ́n;o pa wọ́n mọ́ kúrò ninu rìkíṣí àwọn eniyan;o sì pa wọ́n mọ́ lábẹ́ ààbò rẹ,kúrò lọ́wọ́ ẹnu àwọn ẹlẹ́jọ́ wẹ́wẹ́.

21. Ẹni ìyìn ni OLUWA, nítorí pé, lọ́nà ìyanu,ó fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn mí,nígbà tí ilẹ̀ ká mi mọ́.

22. Ẹ̀rù bà mí, mo sì sọ pé,“A lé mi jìnnà kúrò ní iwájú rẹ.”Ṣugbọn o gbọ́ ẹ̀bẹ̀ minígbà tí mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́.

23. Ẹ fẹ́ràn OLUWA, gbogbo ẹ̀yin olódodo,OLUWA a máa ṣọ́ àwọn olóòótọ́,a sì máa san àlékún ẹ̀san fún àwọn agbéraga.

Orin Dafidi 31