Orin Dafidi 31:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA, ìwọ ni mo sá di,má jẹ́ kí ojú tì mí lae;gbà mí, nítorí olóòótọ́ ni ọ́.

2. Dẹ etí sí mi, yára gbà mí.Jẹ́ àpáta ààbò fún mi;àní ilé ààbò tó lágbára láti gbà mí là.

3. Ìwọ ni àpáta ati ilé ààbò mi;nítorí orúkọ rẹ, máa tọ́ mi kí o sì máa fọ̀nà hàn mí.

Orin Dafidi 31