1. N óo yìn ọ́, OLUWA,nítorí pé o ti yọ mí jáde;o kò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi ó yọ̀ mí.
2. OLUWA, Ọlọrun mi, mo ké pè ọ́,o sì wò mí sàn.
3. OLUWA, o ti yọ mí kúrò ninu isà òkúo sọ mí di ààyè láàrin àwọn tíwọ́n ti wọ inú kòtò.
4. Ẹ kọ orin ìyìn sí OLUWA, ẹ̀yin olùfọkànsìn rẹ̀,kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ̀.