Orin Dafidi 3:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA, àwọn ọ̀tá mi pọ̀ pupọ!Ọ̀pọ̀ ni ó ń dìde sí mi!

2. Ọpọlọpọ ni àwọn tí ń sọ kiri pé,Ọlọrun kò ní gbà mí sílẹ̀!

3. Ṣugbọn ìwọ OLUWA ni ààbò mi,ògo mi, ati ẹni tí ó fún mi ní ìgboyà.

4. Mo ké pe OLUWA,ó sì dá mi lóhùn láti òkè mímọ́ rẹ̀ wá.

Orin Dafidi 3