Orin Dafidi 27:10-13 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Bí baba ati ìyá mi tilẹ̀ kọ̀ mí sílẹ̀,OLUWA yóo tẹ́wọ́gbà mí.

11. Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, OLUWA,kí o sì tọ́ mi sí ọ̀nà títẹ́jú rẹ,nítorí àwọn ọ̀tá mi.

12. Má fi mí lé ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi lọ́wọ́;nítorí pé àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde sí mi,ètè wọn sì kún fún ọ̀rọ̀ ìkà.

13. Mo gbàgbọ́ pé n óo rí oore OLUWA gbàní ilẹ̀ alààyè.

Orin Dafidi 27