24. Nítorí pé kò fi ojú pa ìjìyà àwọn tí à ń jẹ níyà rẹ́;kò sì ṣá wọn tì,bẹ́ẹ̀ ni kò fi ojú pamọ́ fún wọn,ṣugbọn ó gbọ́ nígbà tí wọ́n ké pè é.
25. Ìwọ ni n óo máa yìn láàrin àwùjọ àwọn eniyan;n óo san ẹ̀jẹ́ mi láàrin àwọn tí ó bẹ̀rù OLUWA.
26. Àwọn tí ojú ń pọ́n yóo jẹ àjẹyó;àwọn tí ń wá OLUWA yóo yìn ín!Kí ẹ̀mí wọn ó gùn!
27. Gbogbo ayé ni yóo ranti OLUWAwọn yóo sì pada sọ́dọ̀ rẹ̀;gbogbo ẹ̀yà àwọn orílẹ̀-èdèni yóo sì júbà níwájú rẹ̀.
28. Nítorí OLUWA ló ni ìjọba,òun ní ń jọba lórí gbogbo orílẹ̀-èdè.
29. Gbogbo àwọn agbéraga láyé ni yóo wólẹ̀ níwájú rẹ̀;gbogbo ẹni tí yóo fi ilẹ̀ bora bí aṣọni yóo wólẹ̀ níwájú rẹ̀,àní, gbogbo àwọn tí kò lè dá sọ ara wọn di alààyè.