Orin Dafidi 20:7-9 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀lé kẹ̀kẹ́ ogun,àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀lé ẹṣin,ṣugbọn ní tiwa, àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ OLUWA Ọlọrun wa.

8. Àwọn óo kọsẹ̀, wọn óo sì ṣubú,ṣugbọn àwa óo dìde, a óo sì dúró ṣinṣin.

9. Fún ọba ní ìṣẹ́gun, OLUWA;kí o sì dá wa lóhùn nígbà tí a bá ń ké pè ọ́.

Orin Dafidi 20