6. Ninu ìpọ́njú mi mo ké pe OLUWA,Ọlọrun mi ni mo ké pè.Ó gbọ́ ohùn mi láti inú ilé mímọ́ rẹ̀,ó sì tẹ́tí sí igbe mi.
7. Ilẹ̀ ayé wárìrì, ó sì mì tìtì,ìpìlẹ̀ àwọn òkè mì jìgìjìgì;wọ́n wárìrì nítorí tí ó bínú.
8. Èéfín ṣẹ́ jáde láti ihò imú rẹ̀,iná ajónirun yọ jáde láti ẹnu rẹ̀;ẹ̀yinná sì ń jò bùlà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá.
9. Ó dẹ ojú ọ̀run sílẹ̀, ó sì sọ̀kalẹ̀ wá,ìkùukùu tó ṣókùnkùn biribiri sì wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.
10. Ó gun orí Kerubu, ó sì fò,ó fò lọ sókè lórí ìyẹ́ apá afẹ́fẹ́.
11. Ó fi òkùnkùn bora bí aṣọ,ìkùukùu tí ó ṣókùnkùn, tí ó sì kún fún omini ó fi ṣe ìbòrí.
12. Ninu ìmọ́lẹ̀ níwájú rẹ,ẹ̀yinná ati yìnyín ń fọ́n jáde,láti inú ìkùukùu.
13. OLUWA sán ààrá láti ọ̀run,Ọ̀gá Ògo fọhùn, òjò dídì ati ẹ̀yinná sì fọ́n jáde.
14. Ó ta ọfà rẹ̀ jáde, ó sì fọ́n wọn ká,ó jẹ́ kí mànàmáná kọ, ó sì tú wọn ká.