Orin Dafidi 18:45-49 BIBELI MIMỌ (BM)

45. Àyà pá àwọn àlejò,wọ́n sì fi ìbẹ̀rùbojo sá jáde kúrò ní ibi tí wọ́n sápamọ́ sí.

46. OLUWA wà láàyè! Ẹni ìyìn ni àpáta mi!Ẹni àgbéga ni Ọlọrun ìgbàlà mi!

47. Ọlọrun tí ó ń gbẹ̀san fún mi,tí ó sì ń tẹ orí àwọn eniyan ba fún mi;

48. Ọlọrun tí ó gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi;tí ó sì gbé mi ga ju àwọn abínú-ẹni lọ;ìwọ ni o gbà mí lọ́wọ́ àwọn ẹni ipá tí ó dìde sí mi.

49. Nítorí náà ni èmi ó ṣe máa yìn ọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, OLUWA,èmi ó sì máa kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ.

Orin Dafidi 18