Orin Dafidi 147:11-17 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Ṣugbọn inú OLUWA dùn sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,àwọn tí ó ní ìrètí ninu ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.

12. Gbé OLUWA ga, ìwọ Jerusalẹmu!Yin Ọlọrun rẹ, ìwọ Sioni!

13. Ó fún ẹnubodè rẹ ní agbára,ó sì bukun àwọn tí ń gbé inú rẹ.

14. Ó jẹ́ kí alaafia wà ní ààlà ilẹ̀ rẹ,ó sì fi oúnjẹ tí ó dára bọ́ ọ lábọ̀ọ́yó.

15. Ó pàṣẹ lórí ilẹ̀ ayé,àṣẹ rẹ̀ sì múlẹ̀ kíá.

16. Ó da òjò dídì bo ilẹ̀ bí ẹ̀gbọ̀n òwú,ó sì fọ́n ìrì dídì ká bí eérú.

17. Ó sọ yìnyín sílẹ̀ bí òkò,ta ni ó lè fara da òtútù rẹ̀?

Orin Dafidi 147