Orin Dafidi 144:3-8 BIBELI MIMỌ (BM)

3. OLUWA, kí ni eniyan jẹ́, tí o fi ń náání rẹ̀?Kí sì ni ọmọ eniyan tí o fi ń ranti rẹ̀?

4. Eniyan dàbí èémí,ọjọ́ ayé rẹ̀ sì dàbí òjìji tí ń kọjá lọ.

5. OLUWA, fa ojú ọ̀run wá sílẹ̀, kí o sì sọ̀kalẹ̀ wá,fọwọ́ kan àwọn òkè ńlá, kí wọ́n máa rú èéfín.

6. Jẹ́ kí mànàmáná kọ, kí o sì tú wọn ká,ta ọfà rẹ, kí o tú wọn ká.

7. Na ọwọ́ rẹ sílẹ̀ láti òkè,kí o yọ mí ninu ibú omi;kí o sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn àjèjì,

8. tí ẹnu wọn kún fún irọ́,tí ọwọ́ ọ̀tún wọn sì kún fún èké.

Orin Dafidi 144