Orin Dafidi 141:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA, mo ké pè ọ́, tètè wá dá mi lóhùn,tẹ́tí sí ohùn mi nígbà tí mo bá ń ké pè ọ́.

2. Jẹ́ kí adura mi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ bíi turari,sì jẹ́ kí ọwọ́ adura tí mo gbé sókè dàbí ẹbọ àṣáálẹ́.

3. OLUWA, fi ìjánu sí mi ní ẹnu,sì ṣe aṣọ́nà ètè mi.

4. Má jẹ́ kí ọkàn mi fà sí ibi, má sì jẹ́ kí n lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ìkà.Má jẹ́ kí n bá àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ rìn pọ̀,má sì jẹ́ kí n jẹ ninu oúnjẹ àdídùn wọn.

5. N ò kọ̀ kí ẹni rere bá mi wí,n ò kọ̀ kí ó nà mí;kí ó ṣá ti fi ìfẹ́ bá mi wí.Ṣugbọn má jẹ́ kí eniyan burúkú tilẹ̀ ta òróró sí mi lórí,nítorí pé nígbàkúùgbà ni mò ń fi adura tako ìwà ibi wọn.

6. Nígbà tí ọwọ́ àwọn tí yóo dá wọn lẹ́bi bá tẹ̀ wọ́n,wọn óo gbà pé, òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ OLUWA.

Orin Dafidi 141