11. Má jẹ́ kí abanijẹ́ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ lórí ilẹ̀ náà;jẹ́ kí oníwà ipá ko àgbákò kíákíá.
12. Mo mọ̀ pé OLUWA yóo gba ọ̀ràn olùpọ́njú rò,yóo sì ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn aláìní.
13. Dájúdájú, àwọn olódodo yóo máa fi ọpẹ́ fún ọ;àwọn olóòótọ́ yóo sì máa gbé níwájú rẹ.